God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi; ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà: nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, kí o sì máa ṣe rere; torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀.
Ṣe inú dídùn sí Olúwa; òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀.
Fi ọ̀nà rẹ lé Olúwa lọ́wọ́; gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é.
Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan.
Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ.
Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà.
ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú, nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.
nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.
Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin, àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé.
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé. Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù; wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.
nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà, àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.
Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá, nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.
Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn; àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.
Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi, nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
Dúró de Olúwa, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́. Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà; nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.
Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa; òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n; yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.
Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀. Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin, ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ; kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.