Skip to content
Òwe 5:9-21

Òwe 5:9-21

9
àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò gbé gbogbo ọlá rẹ lé ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti ọjọ́ ayé rẹ fún ìkà ènìyàn.
10
Kí a má ba à fi ọrọ̀ rẹ fún àjèjì ènìyàn, kí làálàá rẹ sì sọ ilé ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.
11
Ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ ìwọ yóò kérora, nígbà tí agbára rẹ àti ara rẹ bá ti joro tán.
12
Ìwọ yóò wí pé, “Mo ti kórìíra ẹ̀kọ́ tó! Ọkàn mi ṣe wá kórìíra ìbáwí!
13
N kò gbọ́rọ̀ sí àwọn olùkọ́ mi lẹ́nu, tàbí kí n fetí sí àwọn tí ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́.
14
Mo ti bẹ̀rẹ̀ ìparun pátápátá ní àárín gbogbo àwùjọ ènìyàn.”
15
Mu omi láti inú kànga tìrẹ, omi tí ń sàn láti inú kànga rẹ.
16
Ó ha yẹ kí omi ìsun rẹ kún àkúnya sí ojú ọ̀nà àti odò tí ń sàn lọ sí àárín ọjà?
17
Jẹ́ kí wọn jẹ́ tìrẹ nìkan, má ṣe ṣe àjọpín wọn pẹ̀lú àjèjì láéláé.
18
Jẹ́ kí orísun rẹ kí ó ní ìbùkún; kí ìwọ ó sì máa yọ nínú aya ìgbà èwe rẹ.
19
Abo àgbọ̀nrín tó dára, ìgalà tí ó wu ni jọjọ, jẹ́ kí ọmú rẹ̀ kí ó máa fi ayọ̀ fún ọ nígbà gbogbo, kí o sì máa yọ̀ nínú ìfẹ́ rẹ̀ nígbàkígbà.
20
Ọmọ mi, èéṣe tí ìwọ ó fi máa yọ̀ nínú ìfẹ́ obìnrin panṣágà, tí ìwọ ó sì fi dì mọ́ ìyàwó ẹlòmíràn?
21
Nítorí ọ̀nà ènìyàn kò fi ara sin rárá fún Olúwa Ó sì ń gbé gbogbo ọ̀nà rẹ̀ yẹ̀ wò.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options