Filipi 3:1-9
1
Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò.
2
Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà.
3
Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara.
4
Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara. Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀,
5
ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi;
6
ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.
7
Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi.
8
Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi,
9
kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.
Settings