Fò sí àkóónú
Numeri 32:34-42

Ìgbékalẹ̀ àti kíkọ́ àwọn ìlú

Numeri 32:34-42
34
Àwọn ará Gadi wọ́n kọ́ Diboni, Atarotu, Aroeri;
35
pẹ̀lú Atrotu Ṣofani, Jaseri, àti Jogbeha,
36
pẹ̀lú Beti-Nimra, àti Beti-Harani ìlú olódi, àti agbo fún àgùntàn.
37
Àwọn ọmọ Reubeni sì kọ́ Heṣboni, Eleale, Kiriataimu,
38
pẹ̀lú Nebo pẹ̀lú Baali-Meoni (wọ́n pàrọ̀ orúkọ wọn) àti Sibma. Wọ́n sì sọ ìlú tí wọ́n tún kọ́ ní orúkọ mìíràn.
39
Àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase lọ sí Gileadi, wọ́n sì lé àwọn ọmọ Amori tí ó wà níbẹ̀.
40
Mose sì fi àwọn ọmọ Gileadi fún àwọn ọmọ Makiri àwọn ìran Manase, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.
41
Jairi, ọmọ Manase gba ibùjókòó wọn, ó sì pè wọ́n ní Haffotu Jairi.
42
Noba gba Kenati àti àwọn ìtẹ̀dó rẹ̀, ó sì pè é ní Noba lẹ́yìn orúkọ ara rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options