Skip to content
Matiu 16:11-25

Matiu 16:11-25

11
Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.”
12
Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi.
13
Nígbà tí Jesu sì dé Kesarea-Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi Ọmọ Ènìyàn pè?”
14
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn kan ni Johanu onítẹ̀bọmi ni, àwọn mìíràn wí pé, Elijah ni, àwọn mìíràn wí pé, Jeremiah ni, tàbí ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”
15
“Ṣùgbọ́n ẹyin ń kọ?” Ó bi í léèrè pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mi pè?”
16
Simoni Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”
17
Jesu sì wí fún un pé, “Alábùkún fún ni ìwọ Simoni ọmọ Jona, nítorí ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ kọ́ ló fi èyí hàn bí kò ṣe Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.
18
Èmi wí fún ọ, ìwọ ni Peteru àti pé orí àpáta yìí ni èmi yóò kọ́ ìjọ mi lé, àti ẹnu-ọ̀nà ipò òkú kì yóò lè borí rẹ̀.
19
Èmi yóò fún ní àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba Ọ̀run; ohun tí ìwọ bá dè ní ayé, òun ni a ó dè ní ọ̀run. Ohunkóhun tí ìwọ bá sì tú ní ayé yìí, a ó sì tú ní ọ̀run.”
20
Nígbà náà ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni pé Òun ni Kristi náà.
21
Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.
22
Peteru mú Jesu sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa! Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ!”
23
Jesu pa ojú dà, ó sì wí fún Peteru pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe èyí ti ṣe ti ènìyàn.”
24
Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
25
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options