Luku 19:39-48
39
Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”
40
Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”
41
Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó síjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí,
42
Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ.
43
Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo.
44
Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”
45
Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde;
46
Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọ́ṣà.”
47
Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á.
48
Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Settings