Joṣua 2:16-24
16
Ó sì ti sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí orí òkè, kí ẹ sì fi ara pamọ́ níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta kí àwọn tí ń lépa yín má ba à rí i yín títí tí wọn yóò fi darí. Lẹ́yìn náà kí ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ.”
17
Àwọn arákùnrin náà sì sọ fún un pé, “Kí ọrùn un wa ba à lè mọ́ kúrò nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú yìí.
18
Nígbà tí àwa bá wọ ilé è rẹ, ìwọ yóò so okùn aláwọ̀ aró yìí sí ojú fèrèsé èyí tí ìwọ fi sọ̀ wá kalẹ̀, kí ìwọ kí ó mú baba rẹ, ìyá rẹ, àwọn arákùnrin in rẹ àti gbogbo ìdílé è rẹ kí wọ́n wá sí inú ilé è rẹ.
19
Bí ẹnikẹ́ni bá jáde sí ìta láti inú ilé è rẹ sí inú ìgboro ìlú, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò sì wà ní orí ara rẹ̀; ẹ̀bi rẹ̀ yóò sì wà lórí i rẹ̀. Fún ẹnikẹ́ni tí ó bá wà nínú ilé pẹ̀lú rẹ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò wà ní orí i wa bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kàn án.
20
Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò bọ́ nínú ìbúra tí ìwọ mú wa bú.”
21
Ó dáhùn pé, “Ó dára bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ó rí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí sọ.” Ó sì rán wọn lọ wọ́n sì lọ. Ó sì so okùn òdòdó náà sí ojú fèrèsé.
22
Nígbà tí wọ́n kúrò, wọ́n sì lọ sí orí òkè wọ́n sì dúró ní ibẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́ta, títí àwọn alépa fi wá wọn ní gbogbo ọ̀nà wọ́n sì padà láìrí wọn.
23
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin méjì náà padà. Wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, wọ odò, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ọmọ Nuni wọ́n sì sọ fún un gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn.
24
Wọ́n sì sọ fún Joṣua, “Nítòótọ́ ni Olúwa tí fi gbogbo ilẹ̀ náà lé wa lọ́wọ́; gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà ni ìbẹ̀rùbojo ti mú nítorí i wa.”
Settings