Johanu 12:40-50
40
“Ó ti fọ́ wọn lójú, Ó sì ti sé àyà wọn le; kí wọn má ba à fi ojú wọn rí, kí wọn má ba à fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn má ba à yípadà, kí èmi má ba à mú wọn láradá.”
41
Nǹkan wọ̀nyí ni Isaiah wí, nítorí ó ti rí ògo rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀.
42
Síbẹ̀ ọ̀pọ̀ nínú àwọn olórí gbà á gbọ́ pẹ̀lú; ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisi wọn kò jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má ba à yọ wọ́n kúrò nínú Sinagọgu,
43
nítorí wọ́n fẹ́ ìyìn ènìyàn ju ìyìn ti Ọlọ́run lọ.
44
Jesu sì kígbe ó sì wí pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, èmi kọ́ ni ó gbàgbọ́ ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi.
45
Ẹni tí ó bá sì rí mi, ó rí ẹni tí ó rán mi.
46
Èmi ni ìmọ́lẹ̀ tí ó wá sí ayé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà mí gbọ́ má ṣe wà nínú òkùnkùn.
47
“Bí ẹnikẹ́ni bá sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò sì pa wọ́n mọ́, èmi kì yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ nítorí tí èmi kò wá láti ṣe ìdájọ́ ayé, bí kò ṣe láti gba ayé là.
48
Ẹni tí ó bá kọ̀ mí, tí kò sì gba ọ̀rọ̀ mi, ó ní ẹnìkan tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀; ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ, òun náà ni yóò ṣe ìdájọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
49
Nítorí èmi kò dá ọ̀rọ̀ sọ fún ara mi, ṣùgbọ́n Baba tí ó rán mi, ni ó ti fún mi ní àṣẹ, ohun tí èmi ó sọ, àti èyí tí èmi ó wí.
50
Èmi sì mọ̀ pé ìyè àìnípẹ̀kun ni òfin rẹ̀, nítorí náà, àwọn ohun tí mo bá wí, gẹ́gẹ́ bí Baba ti sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni mo wí!”
Settings