Skip to content
Jobu 40:15-24

Jobu 40:15-24

15
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi Behemoti, tí mo dá pẹ̀lú rẹ, òun a máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.
16
Wò o nísinsin yìí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.
17
Òun a máa jù ìrù rẹ̀ bí i igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dìjọ pọ̀.
18
Egungun rẹ̀ ní ògùṣọ̀ idẹ, Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.
19
Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; síbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20
Nítòótọ́ òkè ńlá ńlá ní i mu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko igbó máa ṣiré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀.
21
Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótusì, lábẹ́ eèsún àti ẹrẹ̀.
22
Igi lótusì síji wọn bò o; igi arọrọ odò yí i káàkiri.
23
Kíyèsi i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jordani ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.
24
Ẹnìkan ha lè mú un ní ojú rẹ̀, tàbí dẹkùn fún tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options