Skip to content
Jeremiah 38:1-13

Jeremiah 38:1-13

1
Ṣefatia ọmọ Mattani, Gedaliah ọmọ Paṣuri, Jehukali ọmọ Ṣelemiah, àti Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ ohun tí Jeremiah ń sọ fún àwọn ènìyàn nígbà tí ó sọ wí pé,
2
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá dúró nínú ìlú yìí yóò kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tó bá lọ sí Babeli yóò yè; yóò sá àsálà, yóò sì yè.’
3
Àti pé èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Ìdánilójú wà wí pé a ó fi ìlú náà lé ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun ọba Babeli; tí yóò sì kó wa nígbèkùn.’ ”
4
Nígbà náà ni àwọn ìjòyè wí fún ọba pé, “Ó yẹ kí a pa ọkùnrin yìí; ó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ-ogun tókù nínú ìlú pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn nípa ohun tí ó ń sọ fún wọn. Ọkùnrin yìí kò fẹ́ ìre fún àwọn ènìyàn bí kò ṣe ìparun.”
5
Sedekiah ọba sì wí pé, “Ó wà lọ́wọ́ yín. Ọba kò lè ṣe ohunkóhun láti takò yín.”
6
Wọ́n gbé Jeremiah sọ sínú ihò Malkiah, ọmọ ọba, tí ó wà ní àgbàlá ilé túbú; wọ́n fi okùn sọ Jeremiah kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ihò; kò sì ṣí omi nínú ihò náà bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀, Jeremiah sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ náà.
7
Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini.
8
Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé,
9
“Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”
10
Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.”
11
Ebedimeleki kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremiah lọ nínú kànga.
12
Ebedimeleki ará Kuṣi sọ fún Jeremiah pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremiah sì ṣe bẹ́ẹ̀.”
13
Báyìí ni wọ́n ṣe fi okùn yọ Jeremiah jáde, wọ́n sì mu un gòkè láti inú ihò wá, Jeremiah sì wà ní àgbàlá ilé túbú.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options