Skip to content
Gẹnẹsisi 8:13-22

Gẹnẹsisi 8:13-22

13
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ní ọdún kọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta (601) ni omi náà gbẹ kúrò lórí ilẹ̀; Noa sì ṣí ọkọ̀, ó sì ri pé ilẹ̀ ti gbẹ.
14
Ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ilẹ̀ ti gbẹ pátápátá.
15
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé.
16
“Jáde kúrò nínú ọkọ̀, ìwọ àti aya rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti àwọn aya wọn.
17
Kó gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí ó wà pẹ̀lú rẹ jáde: àwọn ẹyẹ, ẹranko àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀, kí wọn lè bí sí i, kí wọn sì pọ̀ sí i, kí wọn sì máa gbá yìn lórí ilẹ̀.”
18
Noa, àwọn ọmọ rẹ̀, aya rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì jáde.
19
Gbogbo àwọn ẹranko àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀ àti gbogbo ẹyẹ pátápátá ni ó jáde kúrò nínú ọkọ̀, ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ní irú tiwọn.
20
Noa sì mọ pẹpẹ fún Olúwa, ó sì mú lára àwọn ẹran tí ó mọ́ àti ẹyẹ tí ó mọ́, ó sì fi rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ.
21
Olúwa sì gbọ́ òórùn dídùn; ó sì wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò tún fi ilẹ̀ ré nítorí ènìyàn mọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èrò inú rẹ̀ jẹ́ ibi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá, èmi kì yóò pa gbogbo ohun alààyè run mọ́ láé, bí mo ti ṣe.
22
“Níwọ́n ìgbà tí ayé bá sì wà, ìgbà ọ̀gbìn àti ìgbà ìkórè ìgbà òtútù àti ìgbà ooru, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò, ìgbà ọ̀sán àti ìgbà òru, yóò wà títí láé.”
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options