Gẹnẹsisi 8:6-12
6
Lẹ́yìn ogójì ọjọ́, Noa sí fèrèsé tí ó ṣe sára ọkọ̀.
7
Ó sì rán ẹyẹ ìwò kan jáde, tí ó ń fò káàkiri síwá àti sẹ́yìn títí omi fi gbẹ kúrò ní orí ilẹ̀.
8
Ó sì rán àdàbà kan jáde láti wò ó bóyá omi ti gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.
9
Ṣùgbọ́n àdàbà náà kò rí ìyàngbẹ ilẹ̀ bà lé nítorí omi kò tí ì tan lórí ilẹ̀, ó sì padà sọ́dọ̀ Noa. Noa na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú ẹyẹ náà wọlé sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nínú ọkọ̀.
10
Ó sì dúró fún ọjọ́ méje sí i; ó sì tún rán àdàbà náà jáde láti inú ọkọ̀.
11
Nígbà tí àdàbà náà padà sọ́dọ̀ rẹ̀ ní àṣálẹ́, ó já ewé igi olifi tútù há ẹnu! Nígbà náà ni Noa mọ̀ pé omi ti ń gbẹ kúrò lórí ilẹ̀.
12
Noa tún mú sùúrù fún ọjọ́ méje, ó sì tún rán àdàbà náà jáde, ṣùgbọ́n àdàbà náà kò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́.
Settings