Skip to content
Gẹnẹsisi 24:29-53

Gẹnẹsisi 24:29-53

29
Rebeka ní arákùnrin tí ń jẹ́ Labani; Labani sì sáré lọ bá ọkùnrin náà ní etí odò.
30
Bí ó sì ti rí òrùka imú àti ẹ̀gbà ní ọwọ́ arábìnrin rẹ̀ tí ó sì tún gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkùnrin náà sọ fún òun, ó jáde lọ bá ọkùnrin náà, ó sì bá a, ó dúró ti ìbákasẹ wọ̀n-ọn-nì ní ẹ̀bá ìsun omi.
31
Ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Wá, ìwọ ẹni ìbùkún Olúwa, èéṣe tí o dúró sí ìta níhìn-ín? Mo ti pèsè ààyè sílẹ̀ fún ọ àti ààyè fún àwọn ìbákasẹ rẹ.”
32
Ọkùnrin náà sì bá Labani lọ ilé, ó sì tú ẹrù orí ìbákasẹ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fún wọn ni koríko àti oúnjẹ. Ó sì bu omi fún ọkùnrin náà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ láti wẹ ẹsẹ̀ wọn.
33
Wọ́n sì gbé oúnjẹ síwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Èmi kò ní jẹun àyàfi bí mo bá sọ ohun tí mo ní í sọ.” Labani sì wí pé, “Kò burú, sọ ọ́.”
34
Nítorí náà, ó wí pé, “Ìránṣẹ́ Abrahamu ni èmi.
35
Olúwa sì ti bùkún olúwa mi gidigidi. Ó sì ti di ọlọ́rọ̀, Ó sì ti fún un ní àgùntàn, màlúù, àti fàdákà àti wúrà, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin àti ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
36
Sara aya olúwa mi sì ti bí ọmọkùnrin kan fún un, ní ìgbà ogbó rẹ̀, olúwa mi sì ti fún ọmọ náà ní ohun gbogbo tí ó ní.
37
Olúwa mi sì ti mú mi búra wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani, ní ilẹ̀ ibi tí èmi ń gbé,
38
ṣùgbọ́n lọ sí ìdílé baba mi láàrín àwọn ìbátan mi kí o sì fẹ́ aya fún ọmọ mi.’
39
“Mo sì bí olúwa mi léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà kò bá fẹ́ bá mi wá ń kọ́?’
40
“Ó sì dáhùn wí pé, ‘Olúwa, níwájú ẹni tí èmi ń rìn yóò rán Angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ yóò sì jẹ́ kí o ṣe àṣeyọrí ní ìrìnàjò rẹ, kí ìwọ kí ó ba le fẹ́ aya fún ọmọ mi, láàrín àwọn ìbátan mi, àti láàrín àwọn ìdílé baba mi.
41
Nígbà tí ìwọ bá lọ sí ọ̀dọ̀ ìdílé baba mi (gẹ́gẹ́ bí mo tí wí), nígbà náà ni ìwọ tó bọ́ nínú ìbúra yìí.’
42
“Nígbà tí mo dé ibi ìsun omi lónìí, mo wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, bí ìwọ bá fẹ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lórí ohun tí mo bá wá yìí.
43
Wò ó, mo dúró ní ẹ̀bá ìsun omi yìí, kí ó ṣe pé, nígbà tí wúńdíá kan bá jáde wá pọn omi, tí èmi sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ìwọ̀nba omi díẹ̀ mu nínú ládugbó rẹ,”
44
tí ó bá sì wí fún mi pé, “Mu ún, èmi yóò sì tún pọn omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú,” jẹ́ kí ẹni náà jẹ́ ẹni tí Olúwa yàn fún ọmọ Abrahamu, olúwa mi.’
45
“Kí n sì tó gbàdúrà tán nínú ọkàn mi, Rebeka jáde wá pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀, ó sì lọ sí ibi ìsun omi ó sì pọn omi. Mo sì wí fun un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi ni omi mu.’
46
“Kíákíá ni ó sọ ìkòkò rẹ̀ kalẹ̀ láti èjìká rẹ̀, ó sì wí fún mi pé, ‘Mu ún, èmi yóò sì tún fún àwọn ìbákasẹ rẹ mu pẹ̀lú.’ Mo sì mu, ó sì tún fún àwọn ìbákasẹ mi mu pẹ̀lú.
47
“Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, ‘Ọmọ ta ní ìwọ í ṣe?’ “Ó sì wí fún mi pé, ‘Ọmọbìnrin Betueli tí í ṣe ọmọ Nahori ni òun, Milka sì ni ìyá òun.’ “Nígbà náà ni mo fi òrùka náà bọ imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ náà si ní ọwọ́.
48
Èmi sì tẹríba, mo sì wólẹ̀ fún Olúwa, mó sì fi ìbùkún fún Ọlọ́run Abrahamu olúwa mi, ẹni tí ó mú mi tọ ọ̀nà títọ́ láti rí ọmọ ọmọ arákùnrin olúwa mi mú wá fún ọmọ rẹ̀.
49
Ǹjẹ́ nísinsin yìí bí ẹ̀yin yóò bá fi inú rere àti òtítọ́ bá olúwa mi lò, ẹ sọ fún mi, bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, ẹ sọ fún mi, kí ń le è mọ ọ̀nà tí èmi yóò yà sí.”
50
Labani àti Betueli sì dáhùn pé, “Lọ́dọ̀ Olúwa ni èyí ti wá, nítorí náà àwa kò le sọ rere tàbí búburú fún ọ.
51
Rebeka nìyí, mú un kí ó máa lọ, kí ó sì di aya ọmọ olúwa à rẹ, bí Olúwa ti fẹ́.”
52
Nígbà tí ọmọ ọ̀dọ̀ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n wí, ó wólẹ̀ níwájú Olúwa.
53
Nígbà náà ni ó kó ohun èlò wúrà àti fàdákà jáde àti aṣọ, ó sì fi wọ́n fún Rebeka, ó fún arákùnrin Rebeka àti ìyá rẹ̀ ní ẹ̀bùn olówó iyebíye pẹ̀lú.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options