Esekiẹli 47:13-23
13
Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu.
14
Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédé ní àárín wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.
15
“Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà: “Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi Òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hetiloni gbà tí Hamati lọ sí Sedadi,
16
Berota àti Sibraimu, èyí tí ó wà ní ààlà láàrín Damasku àti Hamati títí dé Hasari Hatikonu, èyí tí ó wà ní agbègbè Haurani.
17
Ààlà yóò fẹ̀ láti Òkun lọ sí Hasari Enanu, ní apá ààlà ti Damasku, pẹ̀lú ààlà tí Hamati lọ sí apá àríwá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá.
18
Ní ìhà ìlà-oòrùn ààlà yóò wá sí àárín Haurani àti Damasku, lọ sí apá Jordani láàrín Gileadi àti ilẹ̀ Israẹli, títí dé Òkun, àti títí dé Tamari. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà-oòrùn.
19
Ní ìhà gúúsù yóò lọ láti Tamari títí dé ibi omi Meriba Kadeṣi, lẹ́yìn náà ni ìhà Wadi tí Ejibiti lọ sí Òkun ńlá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúúsù.
20
Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, Òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hamati. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀-oòrùn.
21
“Ìwọ ní láti pín ilẹ̀ yìí ní àárín ara yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà Israẹli.
22
Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé ní àárín yín tí ó sì ní àwọn ọmọ. Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Israẹli; papọ̀ mọ́ yin ni kí ẹ pín ìní fún wọn ní àárín àwọn ẹ̀yà Israẹli.
23
Ní àárín gbogbo ẹ̀yà tí àwọn àlejò ń gbé; wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún un,” ní Olúwa Olódùmarè wí.
Settings