Skip to content
Esekiẹli 48:1-7

Esekiẹli 48:1-7

1
“Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn: “Ní òpin àríwá, Dani yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hetiloni lọ sí Lebo-Hamati; Hasari-Enani àti ààlà àríwá tí Damasku tí ó kángun sí Hamati yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà-oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn.
2
Aṣeri yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbègbè Dani láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.
3
Naftali yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Aṣeri láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.
4
Manase yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbègbè Naftali láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.
5
Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.
6
Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn.
7
Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options