Esekiẹli 40:5-19
5
Mo rí ògiri tí ó yí agbègbè ibi mí mọ̀ po. Gígùn ọ̀pá ìwọnlẹ̀ tí ó wà ní ọwọ́ ọkùnrin náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ìlàsí mẹ́rin ẹsẹ̀ bàtà. Ó wọn ògiri náà; ó jẹ́ ìwọ̀nyí ọ̀pá náà ni nínípọn, ó sì jẹ́ ọ̀pá kan ní gíga.
6
Lẹ́yìn náà ni ó wá lọ sí ẹnu-ọ̀nà òde tí ó kọjú sí ìlà-oòrùn. Ó gun àtẹ̀gùn rẹ̀, o sì wọn ìloro ẹnu-ọ̀nà ilé; ó jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn.
7
Yàrá kéékèèké sì jẹ ọ̀pá kan ni gígùn àti ọ̀pá kan ní ibú, ìgbéró ògiri àárín yàrá kéékèèké náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ni nínípọn. Ìloro ẹnu-ọ̀nà náà tí ó kángun sí àtẹ̀wọ ẹnu-ọ̀nà náà tó kọjú sì tẹmpili jẹ́ ọ̀pá kan ní jíjìn.
8
Lẹ́yìn náà, ó wọ̀n ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà:
9
Ó jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́jọ ní jíjìn àtẹ́rígbà rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ méjì ní nínípọn. Ògiri àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà kọjú sí tẹmpili.
10
Ní ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn ni àwọn yàrá kéékèèké mẹ́ta wà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan: mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kọ̀ jú sí ara wọn, ojú ìgbéró ògiri ni ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ bákan náà ní wíwọ̀n.
11
Lẹ́yìn náà ó wọn ìbú à bá wọ ẹnu-ọ̀nà náà; ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, gígùn rẹ̀ sì jẹ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́tàlá.
12
Ní iwájú ọ̀kọ̀ọ̀kan yàrá kéékèèké kọ̀ọ̀kan ní ògiri tí gíga rẹ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan wà, ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àwọn yàrá kéékèèké sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.
13
Lẹ́yìn náà, ó wọn ẹnu-ọ̀nà láti òkè ẹ̀yìn ògiri yàrá kéékèèké kan títí dé òkè ìdojúkọ ọ̀kan; jíjìn sí ara wọn jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n láti odi kan tí ó ṣí sílẹ̀ sí ìdojúkọ ọ̀kan.
14
Ó sí ṣe àtẹ́rígbà ọlọ́gọ́ta ìgbọ̀nwọ́, àní títí dé àtẹ́rígbà ògiri àgbàlá, yí ẹnu-ọ̀nà ká.
15
Láti iwájú ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé títí dé ìparí yàrá kéékèèké náà àti àwọn ìgbéró ògiri nínú ẹnu-ọ̀nà ní a gbé dá jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.
16
Ni a tẹ nínú yíká; àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ní fèrèsé tóóró tí ó wọ inú yíká. Àwọn ògiri wọn ní inú ni a fi pákó tẹ yíká láti ilẹ̀ dé òkè fèrèsé àti láti fèrèsé dé òrùlé.
17
Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ojú òde àgbàlá. Níbẹ̀ mo rí yàrá díẹ̀ àti pèpéle tí a kọ́ yí àgbàlá ká; ọgbọ̀n yàrá wà lẹ́gbẹ̀ pèpéle náà.
18
O ṣe ààlà sí ẹ̀gbẹ́ àwọn ẹnu-ọ̀nà, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà pẹ̀lú gígùn rẹ̀: èyí jẹ́ pèpéle tí ìsàlẹ̀.
19
Lẹ́yìn náà, o wọn jíjìnnà rẹ̀ láti inú ìsàlẹ̀ ẹnu-ọ̀nà títí dé àgbàlá tí inú; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti tí àríwá.
Settings