Skip to content
Eksodu 13:2-15

Eksodu 13:2-15

2
“Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”
3
Nígbà náà ni Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ rántí ọjọ́ òní, ọjọ́ ti ẹ jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin ti ń ṣe ẹrú, nítorí Olúwa mú un yín jáde kúrò ni inú rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ agbára. Ẹ má ṣe jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú.
4
Òní, ní oṣù Abibu (oṣù kẹta ọdún tiwa) lónìí ẹ̀yin ń jáde kúrò ní Ejibiti.
5
Ní ìgbà tí Olúwa mú un yín jáde wá sí ilẹ̀ Kenaani, Hiti, Amori, Hifi àti ilẹ̀ àwọn Jebusi; ilẹ̀ tí ó ti ṣe búra láti fi fún àwọn baba ńlá yín, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ẹ ni láti pa ìsìn yìí mọ́ ní oṣù yìí.
6
Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà nínú àti pé ní ọjọ́ keje ni àjọ yóò wà fún Olúwa.
7
Kí ẹ̀yin ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà fún ọjọ́ méje yìí; kó má ṣe sí ohunkóhun tí a fi ìwúkàrà ṣe ní sàkání yín.
8
Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, ‘Mo ń ṣe èyí nítorí ohun tí Olúwa ṣe fún mi nígbà tí èmi jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.’
9
Ṣíṣe èyí yóò wà fún àmì ní ọwọ́ rẹ, àti bí àmì ìrántí ni iwájú orí rẹ, tí yóò máa rán ọ létí òfin Olúwa ní ẹnu rẹ. Nítorí Olúwa mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá rẹ̀.
10
Ìwọ gbọdọ̀ pa òfin náà mọ́ ní àkókò tí a yàn bí ọdún tí ń gorí ọdún.
11
“Lẹ́yìn tí Olúwa tí mú ọ wá sí ilẹ̀ àwọn ará Kenaani tí ó sì fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra fún ọ àti fún àwọn baba ńlá rẹ̀,
12
ìwọ yóò fi àkọ́bí inú rẹ fún Olúwa. Gbogbo àkọ́bí ti ó jẹ́ akọ ti ẹran ọ̀sìn rẹ ní ó jẹ́ ti Olúwa.
13
Ìwọ yóò fi ọ̀dọ́-àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, ǹjẹ́ kí ìwọ ṣẹ́ ẹ ní ọrùn, gbogbo àkọ́bí ọkùnrin ni kí ìwọ kí ó rà padà.
14
“Yóò sí ṣe ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀, ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín yóò béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni èyí túmọ̀ sí?’ Kí ìwọ kí ó sọ fún wọn pé, ‘Pẹ̀lú ọwọ́ agbára ní Olúwa fi mú wa jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, kúrò ní oko ẹrú.
15
Ní ìgbà ti Farao ṣe orí kunkun, ti ó kọ̀ láti jẹ́ kí a lọ, Olúwa pa gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ejibiti, àti ènìyàn àti ẹranko. Ìdí èyí ni àwa fi ń fi gbogbo àkọ́bí tí í ṣe akọ rú ẹbọ sí Olúwa láti fi ṣe ìràpadà fún àwọn àkọ́bí wa ọkùnrin.’
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options