Skip to content
Daniẹli 9:20-23

Gébúríẹ́lì Farahàn sí Dáníẹ́lì

Daniẹli 9:20-23

Gébúríẹ́lì Farahàn sí Dáníẹ́lì

20
Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀, tí mo sì ń gba àdúrà, tí mo ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn Israẹli ènìyàn mi, tí mo sì ń mú ẹ̀bẹ̀ mi tọ Olúwa Ọlọ́run mi nítorí òkè mímọ́ rẹ.
21
Bí mo ṣe ń gba àdúrà náà lọ́wọ́, Gabrieli ọkùnrin tí mo rí nínú ìran ìṣáájú, yára kánkán wá sí ọ̀dọ̀ mi ní àkókò ẹbọ àṣálẹ́.
22
Ó jẹ́ kí ó yé mi, ó sì wí fún mi pé, “Daniẹli, mo wá láti jẹ́ kí o mọ̀ kí o sì ní òye.
23
Bí o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí nígbà àdúrà, a fún ọ ní ìdáhùn kan, èyí tí mo wá láti sọ fún ọ, nítorí ìwọ jẹ́ àyànfẹ́ gidigidi. Nítorí náà, gba ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò kí ìran náà sì yé ọ:

Kẹ́kọ̀ọ́ ẹsẹ wọ̀nyí

Àlàyé lórí gbogbo ẹsẹ wọ̀nyí, kì í ṣe ẹsẹ kan ṣoṣo

Ibi mìíràn tí Ìwé Mímọ́ ti sọ èyí

  • Saamu 145:18

    Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é, sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
    láti ẹsẹ 20
  • Daniẹli 10:19

    Ó sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ ọkùnrin olùfẹ́ gidigidi. Àlàáfíà ni fún ọ, mú ara le, àní mú ara le.” Nígbà tí ohun bá mi sọ̀rọ̀, a sì mú mi lára le. “Mo sì wí pé, kí olúwa mi kí ó máa sọ̀rọ̀, níwọ̀n ìgbà tí ìwọ ti mú mi ní ara le.”
    láti ẹsẹ 23
  • Daniẹli 9:3

    Nígbà náà, ni mo yípadà sí Olúwa Ọlọ́run, mo bẹ̀ ẹ́ pẹ̀lú àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú àwẹ̀, aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.
    láti ẹsẹ 20
  • Daniẹli 9:4

    Mo gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run mi, mo sì jẹ́wọ́ wí pé: “Ìwọ Olúwa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, pẹ̀lú àwọn tí ó ní ìfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí ó ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
    láti ẹsẹ 20
  • Daniẹli 10:11

    Ó sọ pé, “Daniẹli ẹni tí a yàn fẹ́ gidigidi gba ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́ bá ọ sọ yìí yẹ̀ wò dáradára, kí o sì dìde, nítorí tí a rán mi sí ọ.” Bí ó ṣe sọ èyí fún mi, mo dìde ní ìwárìrì.
    láti ẹsẹ 23
  • Daniẹli 10:12

    Nígbà náà ni ó tẹ̀síwájú, pé, “Má ṣe bẹ̀rù Daniẹli. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fi ọkàn rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ, a gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì wá nítorí ọ̀rọ̀ náà.
    láti ẹsẹ 23
  • Matiu 24:15

    “Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ‘ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ,’ tí ó bá dúró ní ibi mímọ́ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e),
    láti ẹsẹ 23
  • Romu 3:23

    Gbogbo ènìyàn ni ó ṣá ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọ́run,
    láti ẹsẹ 20
  • Daniẹli 8:16

    Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gabrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”
    láti ẹsẹ 21
  • Luku 1:19

    Angẹli náà sì dáhùn ó wí fún un pé, “Èmi ni Gabrieli, tí máa ń dúró níwájú Ọlọ́run; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìròyìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá.
    láti ẹsẹ 21
  • Luku 1:28

    Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”
    láti ẹsẹ 23
  • Orin Solomoni 7:10

    Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe, èmi sì ni ẹni tí ó wù ú.
    láti ẹsẹ 23
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options