Daniẹli 9:24-27
24
“Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan Ibi Mímọ́ Jùlọ.
25
“Nítorí náà, mọ èyí pé, láti ìgbà tí a ti gbé ọ̀rọ̀ náà jáde wí pé kí a tún Jerusalẹmu ṣe, kí a sì tún kọ́, títí dé ìgbà ọmọ-aládé, ẹni òróró náà, alákòóso wa yóò fi dé, ó jẹ́ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó sì tún ìgboro àti yàrá rẹ̀ mọ, ṣùgbọ́n ní àkókò wàhálà ni.
26
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta, a ó ké Ẹni òróró náà kúrò, kò sì ní ní ohun kan. Àwọn ènìyàn ọmọ-aládé náà tí yóò wá ni yóò pa ìlú náà àti ibi mímọ́ run. Òpin yóò dé bí ìkún omi, ogun yóò máa jà títí dé òpin, a sì ti pàṣẹ ìdahoro.
27
Yóò sì fi ìdí i májẹ̀mú kan múlẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan. Ní àárín ọ̀sẹ̀ ni yóò mú òpin bá ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ. Àti lórí apá kan ni yóò dà ìríra tí ó mú ìdahoro wá, títí tí òpin tí a ti pàṣẹ lórí asọnidahoro yóò fi padà fi dé bá a.”
Settings