Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 7:33-57

Ìṣe àwọn Aposteli 7:33-57

33
“Olúwa sì wí fún un pé, ‘Bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.
34
Ní rí rí, mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’
35
“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè.
36
Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ àmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún.
37
“Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’
38
Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa.
39
“Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
40
Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’
41
Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe.
42
Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé: “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli?
43
Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki, àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín, àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n. Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’
44
“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí.
45
Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi.
46
Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu.
47
Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.
48
“Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́, gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49
“ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi? ni Olúwa wí. Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
50
Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’
51
“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí. Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́!
52
Ǹjẹ́ ọ̀kan tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa.
53
Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn angẹli ti fi fún ni, tí ẹ kò sì pa á mọ́.”
54
Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i.
55
Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.
56
Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”
57
Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú,

Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.

Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options