Skip to content
2 Ọba 10:29-36

2 Ọba 10:29-36

29
Bí ó ti wù kí ó rí, Jehu kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, tí ó ṣokùnfà Israẹli láti dá—ti sí sin ẹgbọrọ màlúù wúrà ní Beteli àti Dani.
30
Olúwa sì sọ fún Jehu pé, “Nítorí ìwọ ti ṣe dáradára ní ṣíṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú mi, tí o sì ti ṣe sí ilé Ahabu gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn mi, àwọn ọmọ ọ̀ rẹ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”
31
Síbẹ̀ Jehu kò ṣe pẹ̀lẹ́ láti pa òfin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli mọ́ pẹ̀lú tọkàntọkàn. Òun kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu èyí tí ó ṣokùnfà Israẹli láti dá.
32
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Olúwa ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dín iye Israẹli kù. Hasaeli fi agbára jẹ ọba lórí àwọn ọmọ Israẹli ní gbogbo agbègbè wọn.
33
Ìlà-oòrùn ti Jordani ni gbogbo ilẹ̀ ti Gileadi (ẹ̀kún ilẹ̀ ti ará Gadi, Reubeni, àti Manase) láti Aroeri, tí ó wà létí kòtò Arnoni láti ìhà Gileadi sí Baṣani.
34
Fún ti òmíràn ti iṣẹ́ ìjọba Jehu, gbogbo ohun tí ó ṣe, gbogbo àṣeyọrí rẹ̀, ṣé a kò kọ wọ́n sí inú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
35
Jehu sinmi pẹ̀lú baba a rẹ̀, a sì sin ín sí Samaria Jehoahasi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
36
Àkókò tí Jehu fi jẹ ọba lórí Israẹli ní Samaria jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options