2 Kọrinti 8:16-24
16
Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Titu fún yín.
17
Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkára rẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnra rẹ̀.
18
Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìyìnrere yíká gbogbo ìjọ.
19
Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa.
20
Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín.
21
Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.
22
Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí ni ìtara rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntán ńlá tí ó ní sí yín.
23
Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Titu jẹ́, ẹlẹgbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń béèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kristi.
24
Nítorí náà ẹ fi ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.
Settings