Skip to content
2 Kọrinti 9:1-5

2 Kọrinti 9:1-5

1
Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ.
2
Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè.
3
Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀.
4
Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí.
5
Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options