2 Kronika 32:9-18
9
Lẹ́yìn ìgbà tí Sennakeribu ọba Asiria àti gbogbo àwọn ogun rẹ̀ ń gbógun sí Lakiṣi. Ó rán àwọn ìjòyè rẹ̀ sí Jerusalẹmu pẹ̀lú iṣẹ́ yí fún Hesekiah ọba Juda àti fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí ó wà níbẹ̀:
10
“Èyí ni ohun tí Sennakeribu ọba Asiria wí, ‘Lórí kí ni ẹ̀yin gbé ìgbẹ́kẹ̀lé yín lé, tí ẹ̀yin fi dúró sí Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbógun sí?’
11
Nígbà tí Hesekiah wí pé, ‘Olúwa Ọlọ́run wa yóò gbà wá kúrò lọ́wọ́ ọba Asiria,’ ó ń ṣì yín tọ́ ṣọ́nà, kí ẹ bá lè kú fún ebi àti òǹgbẹ.
12
Ṣé Hesekiah fúnra rẹ̀ kò mú àwọn ọlọ́run ibi gíga àti àwọn pẹpẹ kúrò, tí ó ń wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ kan àti láti sun àwọn ẹbọ lórí rẹ̀’?
13
“Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ ohun tí èmi àti àwọn baba mi ti ṣe sí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn? Ǹjẹ́ àwọn Ọlọ́run tí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní agbára láti gba ilẹ̀ wọn kúrò lọ́wọ́ mi?
14
Ta ni nínú gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí àwọn baba mi ti parun, tí ó le gbà ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ mi, tí Ọlọ́run yín yóò fi le gbà yín lọ́wọ́ mi?
15
Nísinsin yìí, ẹ má ṣe jẹ́ kí Hesekiah ó tàn yín àti ṣì yín tọ́ ṣọ́nà báyìí. Ẹ má ṣe gbà á gbọ́, nítorí tí kò sí ọlọ́run orílẹ̀-èdè mìíràn tàbí ìjọba tí ó ní agbára láti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi tàbí lọ́wọ́ àwọn baba mi, mélòó mélòó wa ni Ọlọ́run yín tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi!”
16
Àwọn ìjòyè Sennakeribu sọ̀rọ̀ síwájú sí i ní ìlòdì sí Olúwa Ọlọ́run àti sí ìránṣẹ́ rẹ̀ Hesekiah.
17
Ọba pẹ̀lú sì kọ àwọn ìwé ní bíbú Olúwa Ọlọ́run Israẹli àti ní sísọ èyí ní ìlòdì sí: “Ní gẹ́gẹ́ bí àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn kò ṣe gba àwọn ènìyàn wọn kúrò lọ́wọ́ mi. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run Hesekiah kì yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi.”
18
Lẹ́yìn náà wọ́n pè jáde ní èdè Heberu sí àwọn ènìyàn Jerusalẹmu tí ó wà lára ògiri, láti dá ọjọ́ fún wọn, ki wọn kí ó lè fi agbára mú ìlú náà.
Settings