2 Kronika 32:22-27
22
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yọ Hesekiah àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu kúrò lọ́wọ́ Sennakeribu ọba Asiria àti lọ́wọ́ gbogbo àwọn mìíràn. Ó tọ́jú wọn ní gbogbo ọ̀nà.
23
Ọ̀pọ̀ mú ọrẹ wá sí Jerusalẹmu fún Olúwa àti àwọn ẹ̀bùn iyebíye fún Hesekiah ọba Juda. Ó sì gbéga lójú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn náà.
24
Ní ọjọ́ wọ́n nì Hesekiah ṣe àárẹ̀, ó sì dójú ikú. Ó gbàdúrà sí Olúwa tí ó dá a lóhùn, tí ó sì fún un ní àmì àgbàyanu.
25
Ṣùgbọ́n ọkàn Hesekiah ṣe ìgbéraga, kò sì kọbi ara sí i inú rere tí a fihàn án. Nítorí náà, ìbínú Olúwa wà lórí rẹ̀ àti lórí Juda àti Jerusalẹmu.
26
Nígbà náà ni Hesekiah ronúpìwàdà ní ti ìgbéraga ọkàn rẹ̀, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu sì ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí náà, ìbínú Olúwa kò wá sí orí wọn ní ìgbà àwọn ọjọ́ Hesekiah.
27
Hesekiah ní ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ńlá àti ọlá, ó sì ṣe àwọn ilé ìṣúra fún fàdákà àti wúrà rẹ̀ àti fún àwọn òkúta iyebíye rẹ̀, àwọn tùràrí olóòórùn dídùn àwọn àpáta àti gbogbo oríṣìí nǹkan iyebíye.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì: Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™, © 2009, 2017 Biblica, Inc. · CC BY-SA 4.0“Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc., used with permission.
Settings