Skip to content
2 Kronika 26:6-15

2 Kronika 26:6-15

6
Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini.
7
Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni.
8
Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá.
9
Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le
10
Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.
11
Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba.
12
Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600).
13
Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀.
14
Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun.
15
Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options