1 Kronika 6:39-66
39
Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀: Asafu ọmọ Berekiah, ọmọ Ṣimea,
40
ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah
41
ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,
42
ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,
43
ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;
44
láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluki,
45
ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,
46
ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri,
47
ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
48
Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
49
Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.
50
Wọ̀nyí ni àwọn ìránṣẹ́ Aaroni: Eleasari ọmọ rẹ̀, Finehasi ọmọ rẹ̀, Abiṣua ọmọ rẹ̀,
51
Bukki ọmọ rẹ̀, Ussi ọmọ rẹ̀, Serahiah ọmọ rẹ̀,
52
Meraioti ọmọ rẹ̀, Amariah ọmọ rẹ̀, Ahitubu ọmọ rẹ̀,
53
Sadoku ọmọ rẹ̀ àti Ahimasi ọmọ rẹ̀.
54
Wọ̀nyí ni ibùgbé wọn tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbègbè wọn (tí a fi lé àwọn ìran ọmọ Aaroni lọ́wọ́ tí ó wá láti ẹ̀yà Kohati, nítorí kèké alákọ́kọ́ jẹ́ tiwọn).
55
A fún wọn ní Hebroni ní Juda pẹ̀lú àyíká pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
56
Ṣùgbọ́n àwọn pápá àti ìletò tí ó yí ìlú ńlá náà ká ni a fi fún Kalebu ọmọ Jefunne.
57
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìran ọmọ Aaroni ni a fún ní Hebroni (ìlú ti ààbò), àti Libina, Jattiri, Eṣitemoa,
58
Hileni, Debiri,
59
Aṣani, Jutta àti Beti-Ṣemeṣi lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ rẹ̀.
60
Àti láti inú ẹ̀yà Benjamini, a fún wọn ní Gibeoni, Geba, Alemeti àti Anatoti lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn. Àwọn ìlú wọ̀nyí, tí a pín láàrín àwọn ẹ̀yà Kohati jẹ́ mẹ́tàlá ní gbogbo rẹ̀.
61
Ìyókù àwọn ìran ọmọ Kohati ní a pín ìlú mẹ́wàá fún láti àwọn ìdílé ní ti ààbọ̀ ẹ̀yà Manase.
62
Àwọn ìran ọmọ Gerṣoni, sí ìdílé ni a pín ìlú mẹ́tàlá fún láti ẹ̀yà àwọn ẹ̀yà Isakari, Aṣeri àti Naftali, àti láti apá ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Baṣani.
63
Sebuluni àwọn ìran ọmọ Merari, ìdílé sí ìdílé, ní a pín ìlú méjìlá fún láti ẹ̀yà Reubeni, Gadi àti Sebuluni.
64
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli fún àwọn ará Lefi ní ìlú wọ̀nyí pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
65
Láti ẹ̀yà Juda, Simeoni àti Benjamini ni a pín ìlú tí a ti dárúkọ wọn sẹ́yìn fún.
66
Lára àwọn ìdílé Kohati ni a fún ní ìlú láti ẹ̀yà Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìlú agbègbè wọn.
Settings