1 Kronika 6:16-49
16
Àwọn ọmọ Lefi: Gerṣoni, Kohati àti Merari.
17
Wọ̀nyí ni àwọn orúkọ àwọn ọmọ Gerṣoni: Libni àti Ṣimei.
18
Àwọn ọmọ Kohati: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli.
19
Àwọn ọmọ Merari: Mahili àti Muṣi. Wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ará Lefi tí a kọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí baba wọn.
20
Ti Gerṣoni: Libni ọmọkùnrin rẹ̀, Jahati. Ọmọkùnrin rẹ̀, Simma ọmọkùnrin rẹ̀,
21
Joah ọmọkùnrin rẹ̀, Iddo ọmọkùnrin rẹ̀, Sera ọmọkùnrin rẹ̀ àti Jeaterai ọmọkùnrin rẹ̀.
22
Àwọn ìran ọmọ Kohati: Amminadabu ọmọkùnrin rẹ̀, Kora ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.
23
Elkana ọmọkùnrin rẹ̀, Ebiasafi ọmọkùnrin rẹ̀, Asiri ọmọkùnrin rẹ̀.
24
Tahati ọmọkùnrin rẹ̀, Urieli ọmọkùnrin rẹ̀, Ussiah ọmọkùnrin rẹ̀ àti Saulu ọmọkùnrin rẹ̀.
25
Àwọn ìran ọmọ Elkana: Amasai, Ahimoti
26
Elkana ọmọ rẹ̀, Sofai ọmọ rẹ̀ Nahati ọmọ rẹ̀,
27
Eliabu ọmọ rẹ̀, Jerohamu ọmọ rẹ̀, Elkana ọmọ rẹ̀ àti Samuẹli ọmọ rẹ̀.
28
Àwọn ọmọ Samuẹli: Joẹli àkọ́bí àti Abijah ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì.
29
Àwọn ìran ọmọ Merari: Mahili, Libni ọmọ rẹ̀. Ṣimei ọmọ rẹ̀, Ussa ọmọ rẹ̀.
30
Ṣimea ọmọ rẹ̀, Haggiah ọmọ rẹ̀ àti Asaiah ọmọ rẹ̀.
31
Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀.
32
Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
33
Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,
34
ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
35
ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
36
ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,
37
ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora,
38
ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;
39
Hemani sì darapọ̀ mọ́ Asafu, ẹni tí o sìn ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀: Asafu ọmọ Berekiah, ọmọ Ṣimea,
40
ọmọ Mikaeli, ọmọ Baaseiah, ọmọ Malkiah
41
ọmọ Etini, ọmọ Sera, ọmọ Adaiah,
42
ọmọ Etani, ọmọ Simma, ọmọ Ṣimei,
43
ọmọ Jahati, ọmọ Gerṣoni, ọmọ Lefi;
44
láti ìbákẹ́gbẹ́ wọn, àwọn ará Merari wà ní ọwọ́ òsì rẹ̀: Etani ọmọ Kiṣi, ọmọ Abdi, ọmọ Malluki,
45
ọmọ Haṣabiah, ọmọ Amasiah, ọmọ Hilkiah,
46
ọmọ Amisi, ọmọ Bani, ọmọ Ṣemeri,
47
ọmọ Mahili, ọmọ Muṣi, ọmọ Merari, ọmọ Lefi.
48
Àwọn Lefi ẹgbẹ́ wọn ni wọn yan àwọn iṣẹ́ yòókù ti àgọ́ fún, èyí tí í ṣe ilé Ọlọ́run.
49
Ṣùgbọ́n Aaroni àti àwọn ìran ọmọ rẹ̀ jẹ́ àwọn tí ó gbé ọrẹ kalẹ̀ lórí pẹpẹ ẹbọ sísun àti lórí pẹpẹ tùràrí ní ìbátan pẹ̀lú gbogbo ohun tí a ṣe ní Ibi Mímọ́ Jùlọ. Ṣíṣe ètùtù fún Israẹli, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Mose ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pàṣẹ.
Settings