1 Kronika 4:4-23
4
Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.
5
Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.
6
Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.
7
Àwọn ọmọ Hela: Sereti Sohari, Etani,
8
àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.
9
Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.”
10
Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún mi, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.
11
Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni.
12
Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.
13
Àwọn ọmọ Kenasi: Otnieli àti Seraiah. Àwọn ọmọ Otnieli: Hatati àti Meonotai.
14
Meonotai sì ni baba Ofira. Seraiah sì jẹ́ baba Joabu, baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.
15
Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne: Iru, Ela, àti Naamu. Àwọn ọmọ Ela: Kenasi.
16
Àwọn ọmọ Jehaleeli: Sifi, àti Sifa, Tiria àti Asareeli.
17
Àwọn ọmọ Esra: Jeteri, Meredi, Eferi àti Jaloni. Ọ̀kan lára àwọn aya Meredi sì bí Miriamu, Ṣammai àti Iṣba baba Eṣitemoa.
18
Aya rẹ̀ láti ẹ̀yà Juda sì bí Jaredi baba Gedori, àti Heberi baba Soko àti Jekutieli baba Sanoa. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ọmọbìnrin Farao Bitia, ẹni ti Meredi ti fẹ́.
19
Àwọn ọmọ aya Hodiah arábìnrin Nahamu, baba Keila ará Garimu, àti Eṣitemoa àwọn ará Maakati.
20
Àwọn ọmọ Ṣimoni: Amnoni, Rina, Beni-Hanani àti Tiloni. Àwọn ọmọ Iṣi: Soheti àti Beni-Soheti.
21
Àwọn ọmọ Ṣela ọmọ Juda: Eri baba Leka, Lada baba Meraṣa àti àwọn ìdílé ilé àwọn tí ń hun aṣọ oníṣẹ́ ní Beti-Aṣibea.
22
Jokimu, ọkùnrin Koseba, àti Joaṣi àti Sarafi, olórí ní Moabu àti Jaṣubi Lehemu. (Àkọsílẹ̀ yìí sì wà láti ìgbà àtijọ́.)
23
Àwọn sì ni amọ̀kòkò tí ń gbé ní Netaimu àti Gedera; wọ́n sì dúró níbẹ̀ wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ fún ọba.
Settings