1 Kronika 22:6-16
6
Nígbà náà ó pe Solomoni ọmọ rẹ̀ ó sì sọ fun pé kí ó kọ́ ilé fún un Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.
7
Dafidi sì wí fún Solomoni pé, “Ọmọ mi, mo sì ní-in ní ọkàn mi láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi.
8
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé, ‘Ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, o sì ti ja ọ̀pọ̀ ogun ńlá ńlá, kì í ṣe ìwọ ni yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ lórí ilẹ̀ ní ojú mi.
9
Ṣùgbọ́n ìwọ yóò ní ọmọ tí yóò sì jẹ́ ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ àti onísinmi, Èmi yóò sì fún un ní ìsinmi láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ yíká. Orúkọ rẹ̀ yóò sì máa jẹ́ Solomoni, Èmi yóò sì fi àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ fún Israẹli lásìkò ìjọba rẹ̀.
10
Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’
11
“Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ.
12
Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́.
13
Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́.
14
“Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé Olúwa ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn.
15
Ìwọ sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníṣẹ́ ènìyàn: àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn oníṣọ̀nà òkúta àti àwọn agbẹ́-òkúta, àti gẹ́gẹ́ bí onírúurú ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní gbogbo onírúurú iṣẹ́.
16
Nínú wúrà, fàdákà àti idẹ àti irin oníṣọ̀nà tí kò ní ìwọ̀n. Nísinsin yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
Settings