Fò sí àkóónú

Orin Solomoni8

Ìfẹ́ tí kò ní ìkálọ́wọ́kò

1
Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi, èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà! Èmi ìbá rí ọ ní òde, èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu, wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
2
Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́ èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá mi, ìwọ ìbá kọ́ mi. Èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu, àti oje èso pomegiranate mi.
3
Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.
4
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà. Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè. Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

Àwọn méjèèjì padà wá, wọ́n sì rántí

5
Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù, tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀. Olólùfẹ́ Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.

Agbára ìfẹ́ tí kò ṣẹ́gun

6
Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
7
Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ. Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́, ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀, a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.

Ìmọ̀ràn nípa arábìnrin kékeré

8
Àwa ní arábìnrin kékeré kan, òun kò sì ní ọmú, kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa, ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
9
Bí òun bá jẹ́ ògiri, àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí. Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn, àwa yóò fi pákó kedari dí i.
10
Èmi jẹ́ ògiri, ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́ bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀ bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.

Ọgbà àjàrà Ṣúlámítì tí ó jẹ́ tirẹ̀ nìkan

11
Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá ẹgbẹ̀rún (1,000) fàdákà.
12
Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi; ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni, igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

Pàṣípààrọ̀ ìkẹyìn àti ìpè

13
Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà, àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ, jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!
14
Yára wá, Olùfẹ́ mi, kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin, tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín, lórí òkè òórùn dídùn.
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options