Skip to content

Jobu14

1
“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin, ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
2
Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
3
Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
4
Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!
5
Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
6
Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7
“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
8
Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,
9
síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10
Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù, àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.
11
“Bí omi ti í tán nínú ipa odò, àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12
bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
13
“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14
Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15
Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn; ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi; ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17
A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
18
“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19
Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20
Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ! Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21
Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
22
Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options