- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
Jakọbu5
Listen to this chapter
0:00
0:00
Ìkìlọ̀ sí àwọn ọlọ́rọ̀ aninilára
1
Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín.
2
Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín.
3
Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn.
4
Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
5
Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa.
6
Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín.
Sùúrù nínú ìjìyà
7
Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadà wá Olúwa. Kíyèsi i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.
8
Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀, nítorí ìpadà wá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.
9
Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má ba à dá a yín lẹ́bi: kíyèsi i, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.
10
Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù.
11
Sá à wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fi ara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jobu, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.
Òtítọ́ nínú ọ̀rọ̀
12
Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe ìbúra, ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má ba à bọ́ sínú ẹ̀bi.
Àdúrà ìgbàgbọ́
13
Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́.
14
Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa.
15
Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í.
16
Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.
17
Ènìyàn bí àwa ni Elijah, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà.
18
Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.
Mú ẹni tó ṣìnà padà
19
Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà;
20
jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Reading Width chars
Options
Study Note