Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Walls of the Cities: Figurative of the New Jerusalem

7 ẹsẹ · 8 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Figurative of the New Jerusalem

  1. Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli.

  2. Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.

  3. Ó sì wọn odi rẹ̀ ó jẹ́ ogóje ìgbọ̀nwọ́ lé mẹ́rin (144), gẹ́gẹ́ bí òsùwọ̀n ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni tí angẹli náà.

  4. A sì fi jasperi mọ odi ìlú náà. Ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí tí o mọ́ kedere.

  5. A fi onírúurú òkúta iyebíye ṣe ìpìlẹ̀ ògiri ìlú náà lọ́ṣọ̀ọ́. Ìpìlẹ̀ èkínní jẹ́ jasperi; èkejì, safiru; ẹ̀kẹta, kalkedoni; ẹ̀kẹrin, emeradi;

  6. ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, berili; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti.

  7. Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ perli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán.