Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Toleration

14 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù yóò jókòó lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, ẹnìkan kì yóò sì dẹ́rùbà wọ́n, nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ̀rọ̀.

  2. Gbogbo àwọn ènìyàn ń rìn, olúkúlùkù ni orúkọ ọlọ́run tirẹ̀, ṣùgbọ́n àwa yóò máa rìn ní orúkọ Olúwa. Ọlọ́run wa láé àti láéláé.

  3. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Johanu sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwa rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú wa.”

  4. Jesu sì sọ fún un pé, “Má ṣe dá irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ dúró, nítorí kò sí ẹnìkan ti ó fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóò tún lè máa sọ ohun búburú nípa mi.

  5. Nítorí ẹni tí kò bá kọ ojú ìjà sí wa, ó wà ní ìhà tiwa.

  6. Johanu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́, àwa rí ẹnìkan ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde; àwa sì dá a lẹ́kun, nítorí tí kò bá wa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

  7. Jesu sì wí fún un, pé, “Má ṣe dá a lẹ́kun mọ́: nítorí ẹni tí kò bá lòdì sí i yín, ó wà fún yín.”

  8. Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀.

  9. Ó ń wàásù ìjọba Ọlọ́run, ó ń fi ìgboyà kọ́ni ní àwọn ohun tí i ṣe ti Jesu Kristi Olúwa, ẹnìkan kò si dá a lẹ́kun.

  10. Bí ẹnikẹ́ni bá sì kìlọ̀ fún un yín pé, “A ti fi ẹran yìí rú ẹbọ,” ẹ má ṣe jẹ́ ẹ nítorí ẹni ti o sọ fun ọ àti nítorí ẹ̀rí ọkàn.

  11. Èmi ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀rí ọkàn ẹni tí ó sọ fún ọ kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí kín ni a ó fi dá mi lẹ́jọ́ nítorí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíràn.

  12. Bí èmi ba fi ọpẹ́ jẹ ẹ́, èéṣe tí a fì ń sọ̀rọ̀ mi ní búburú nítorí ohun tí èmi dúpẹ́ fún.

  13. Nítorí náà tí ẹ̀yin bá jẹ tàbí tí ẹ bá mu tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sè, e máa ṣe gbogbo rẹ̀ fún ògo Ọlọ́run.

  14. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ tí ó lè gbé ẹlòmíràn ṣubú ìbá à ṣe Júù tàbí Giriki tàbí ìjọ Ọlọ́run.