Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Thirst

16 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora. Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.

  2. Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè. Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?

  3. Oúnjẹ mi ni omijé mi ní ọ̀sán àti ní òru, nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé, “Ọlọ́run rẹ dà?”

  4. Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí, èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi: èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ, èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.

  5. Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda. Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi, nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ, òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi, ara mi fà sí ọ, ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀ níbi tí kò sí omi.

  6. Èmi na ọwọ́ mi jáde sí ọ: òǹgbẹ rẹ gbẹ ọkàn mi bí i ìyàngbẹ ilẹ̀. Sela.

  7. “Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ, ẹ wá sí ibi omi; àti ẹ̀yin tí kò ní owó; ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ! Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà láìsí owó àti láìdíyelé.

  8. “Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.

  9. Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.

  10. “Ní ọjọ́ náà “àwọn arẹwà wúńdíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin yóò dákú fún òǹgbẹ omi.

  11. Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.

  12. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

  13. Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

  14. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn, tí í ṣe ọjọ́ ńlá àjọ, Jesu dúró, ó sì kígbe wí pé, “Bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó tọ̀ mí wá, kí ó sì mu.

  15. Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.

  16. Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.