Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Thebez

8 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Abimeleki tún lọ sí Tebesi, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

  2. Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sálọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà.

  3. Abimeleki lọ sí ìsàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà. Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún,

  4. obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lu Abimeleki lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí.

  5. Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, “Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’ ” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún un, ó sì kú.

  6. Nígbà tí àwọn ará Israẹli rí i pé Abimeleki kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀.

  7. Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Abimeleki hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin arákùnrin rẹ̀.

  8. Ta ni ó pa Abimeleki ọmọ Jerubu-Beṣeti? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta-ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tebesi? Èéha ti rí tí ẹ̀yin fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún un pé, Uriah ìránṣẹ́ rẹ ará Hiti kú pẹ̀lú.’ ”