Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Law of God: Punishment for disobeying

7 ẹsẹ · 58 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Punishment for disobeying

  1. “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ Olúwa sílẹ̀ tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadi tí ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán,

  2. Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà, àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa; nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn. Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀. Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú mi ẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.”

  3. Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun; ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin, àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu, ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin; àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀, ṣùgbọ́n a ó dójútì yin.

  4. Olúwa sì wí pé, nítorí pé wọ́n ti kọ òfin mi sílẹ̀, èyí tí mo gbé kalẹ̀ níwájú wọn, wọn ṣe àìgbọ́ràn sí wọn, wọn kò sì rìn nínú òfin mi.

  5. Dípò èyí, wọ́n ti tẹ̀lé agídí ọkàn wọn, wọ́n ti tẹ̀lé Baali gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe kọ́ wọn.

  6. Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, “Wò ó, Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ oúnjẹ kíkorò àti láti mu omi májèlé.

  7. Èmi yóò sì tú wọn ká láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, nínú èyí tí àwọn tàbí àwọn baba wọn kò mọ̀. Èmi yóò sì lépa wọn pẹ̀lú idà títí èmi yóò fi pa wọ́n run.”