Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Ishmaelites: Their glory, &c to be diminished

5 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Their glory, &c to be diminished

  1. Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Arabia. Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dedani, tí ó pàgọ́ sínú igbó Arabia,

  2. gbé omi wá fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ; ẹ̀yin tí ó ń gbé Tema, gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.

  3. Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà, kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ, kúrò lọ́wọ́ ọrun tí a fàyọ àti kúrò nínú ìgbóná ogun.

  4. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrín ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ògo ìlú Kedari yóò wá sí òpin.

  5. Àwọn tafàtafà tí ó sálà, àwọn jagunjagun ìlú Kedari kò ní tó nǹkan.” Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ni ó ti sọ̀rọ̀.