Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Feast of Sabbatical Year: Jews threatened for neglecting

6 ẹsẹ · 13 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Jews threatened for neglecting

  1. “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí pé: Mo dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín nígbà tí mo mú wọn kúrò ní Ejibiti; kúrò ní oko ẹrú. Mo wí pé,

  2. ‘Ní ọdún keje, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ tú àwọn Heberu tí wọ́n ti ta ara wọn fún un yín sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti sìn yín fún ọdún mẹ́fà. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ kí wọn kí ó lọ’; ṣùgbọ́n àwọn baba yín kò gbọ́; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí mi.

  3. Láìpẹ́ yìí ẹ ti ronúpìwàdà, ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì ṣe ìtúsílẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Ẹ sì tún bá mi dá májẹ̀mú ní àwọn ilé tí a ti ń pe orúkọ mi.

  4. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yípadà, ẹ sì sọ orúkọ mi di èérí, olúkúlùkù sì mú kí àwọn ẹni rẹ tí ó ti sọ di òmìnira bí ọkàn wọn ti fẹ́ padà; ẹ̀yin sì tún fi wọ́n ṣe ẹrú.

  5. “Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò fetí sí mi nípa ọ̀rọ̀ òmìnira láàrín ẹ̀gbọ́n sí àbúrò, láàrín ẹnìkan sí èkejì rẹ̀. Wò ó, èmi yóò kéde òmìnira fún un yín ni Olúwa wí. Sí idà, sí àjàkálẹ̀-ààrùn, àti sí ìyàn, èmi ó sì fi yín fún ìwọ̀sí ní gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé.

  6. Èmi ó ṣe àwọn ọkùnrin náà tí ó da májẹ̀mú mi, tí kò tẹ̀lé májẹ̀mú tí wọ́n ti dá níwájú mi bí ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n gé sí méjì, tí ó sì kọjá láàrín ìpín méjì náà.