Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Deluge: (Unexpectedness of,) of suddenness of Christ's coming

8 ẹsẹ · 27 abala

Àwọn ẹsẹ nípa (Unexpectedness of,) of suddenness of Christ's coming

  1. “Ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ti ó mọ ọjọ́ àti wákàtí tí òpin náà yóò dé, àwọn angẹli ọ̀run pàápàá kò mọ̀ ọ́n. Àní, ọmọ kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba mi nìkan ṣoṣo ló mọ̀ ọ́n.

  2. Bí ó ṣe rí ní ìgbà ayé Noa, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò sì rí.

  3. Nítorí bí àwọn ọjọ́ náà ti wà ṣáájú ìkún omi, tí wọ́n ń jẹ́ tí wọ́n ń mu, tí wọ́n ń gbéyàwó, tí wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí tí ó fi di ọjọ́ tí Noa fi bọ́ sínú ọkọ̀.

  4. Ènìyàn kò gbàgbọ́ nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ títí tí ìkún omi fi dé nítòótọ́, tí ó sì kó wọn lọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn.

  5. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.

  6. “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọti; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé,

  7. ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọti jáde kúrò ní Sodomu, òjò iná àti sulfuru rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.

  8. “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí Ọmọ Ènìyàn yóò farahàn.