Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Anger of God: Is averted from them that believe
Àwọn ẹsẹ nípa Is averted from them that believe
Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú.
Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”
“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.
Nítorí Ọlọ́run kò rán ọmọ rẹ̀ sí ayé láti dá aráyé lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n kí a le ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là.
Ẹni tí ó bá gbà á gbọ́, a kò ní dá a lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n a ti dá ẹni tí kò gbà á gbọ́ lẹ́jọ́ ná, nítorí tí kò gba orúkọ ọmọ kan ṣoṣo ti Ọlọ́run gbọ́.