Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tahpanhes

7 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Bákan náà, àwọn ọkùnrin Memfisi àti Tafanesi wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.

  2. Nítorí náà, wọn wọ Ejibiti pẹ̀lú àìgbọ́ràn sí àṣẹ Olúwa, wọ́n sì lọ títí dé Tafanesi.

  3. Ní Tafanesi ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá:

  4. “Nígbà tí àwọn Júù ń wòye mú àwọn òkúta pẹ̀lú rẹ, kí o sì rì wọ́n mọ́ inú amọ̀ tí ó wà nínú bíríkì tí ó wà níbi pèpéle ẹnu-ọ̀nà ààfin Farao ní Tafanesi.

  5. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti:

  6. “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli, sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi: ‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’

  7. Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.