Skip to content

Migdol

6 verses · 2 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: tower

30.0200, 32.3700 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Migdol

  1. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Hahirotu láàrín Migdoli òun Òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá Òkun, ní òdìkejì Baali-Ṣefoni.

  2. Wọ́n kúrò ní Etamu, wọ́n padà sí Pi-Hahirotu sí ìlà-oòrùn Baali-Ṣefoni, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀bá Migdoli.

  3. Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá nípa àwọn Júù tí ń gbé ní ìsàlẹ̀ Ejibiti ní Migdoli, Tafanesi àti Memfisi àti ní apá òkè Ejibiti:

  4. “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli, sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi: ‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’

  5. nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi.

  6. “ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí: “ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà láti Migdoli títí dé Siene, wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ; ní Olúwa Olódùmarè wí.