Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Standard

11 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.

  2. “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”

  3. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

  4. Ìwọ lẹ́wà olùfẹ́ mi, bí i Tirsa, ìwọ lẹ́wà bí i Jerusalẹmu, ìwọ ògo bí ogun pẹ̀lú ọ̀págun.

  5. Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?

  6. Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí, “Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà, Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn; wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní èjìká wọn.

  7. Ẹ kọjá, ẹ kọjá ní ẹnu ibodè náà! Ẹ tún ọ̀nà ṣe fún àwọn ènìyàn. Ẹ mọ ọ́n sókè, ṣe ojú ọ̀nà òpópó! Ẹ ṣa òkúta kúrò. Ẹ gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè.

  8. Fi àmì láti sálọ sí Sioni hàn, sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró. Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá, àní ìparun tí ó burú jọjọ.”

  9. Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

  10. “Ẹ sọ ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde, kí ẹ sì gbé àsíá sókè, ẹ kéde rẹ̀ ẹ má sì ṣe bò ó, wí pé, ‘A kó Babeli, ojú tí Beli, a fọ́ Merodaki túútúú, ojú ti àwọn ère rẹ̀, a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’

  11. Gbé àsíá sókè sí odi Babeli! Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí, ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri, ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́ Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde, òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.