Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Spiritual Peace: Is through the atonement of Christ

4 ẹsẹ · 53 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Is through the atonement of Christ

  1. Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa; ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀, àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.

  2. Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín.

  3. Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà

  4. Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.