Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Silver: Dishes
Àwọn ẹsẹ nípa Dishes
Ọrẹ rẹ̀ jẹ́: àwo fàdákà kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádóje ṣékélì àti àwokòtò ti fàdákà tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ àádọ́rin ṣékélì, méjèèjì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́ àwo kọ̀ọ̀kan kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára tí a fi òróró pò gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun jíjẹ;
Wọ̀nyí ni ọrẹ tí àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli mú wá fún ìyàsímímọ́ pẹpẹ nígbà tí wọ́n ta òróró sí i lórí: àwo fàdákà méjìlá, àwokòtò méjìlá, àwo wúrà méjìlá.
Àwo fàdákà kọ̀ọ̀kan wọn àádóje ṣékélì, àwokòtò kọ̀ọ̀kan sì wọn àádọ́rin. Àpapọ̀ gbogbo àwo fàdákà jẹ́ egbèjìlá (2,400) ṣékélì gẹ́gẹ́ bí iye owó ibi mímọ́.