Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shebna

13 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Wọ́n sì pe ọba; àti Eliakimu ọmọ Hilkiah ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọkùnrin Asafu tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn.

  2. Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah, àti Ṣebna àti Joah sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Aramaiki, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Heberu ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”

  3. Nígbà náà Eliakimu ọmọ Hilkiah olùtọ́jú ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé ránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah, pẹ̀lú aṣọ wọn yíya, ó sì wí fún un ohun tí olùdarí pápá ti sọ.

  4. Ó sì rán Eliakimu olùtọ́jú ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti olórí àlùfáà gbogbo wọn sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi.

  5. Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé, fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

  6. Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

  7. “Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.

  8. Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà— ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!

  9. Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ, a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

  10. Ṣebna Eliakimu ọmọ Hilkiah alábojútó ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀.

  11. Lẹ́yìn náà ni Eliakimu, Ṣebna àti Joah sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki, nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.”

  12. Lẹ́yìn náà ni Eliakimu ọmọ Hilkiah alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti Joah ọmọ Asafu akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ Hesekiah pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.

  13. Òun sì rán Eliakimu alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti aṣíwájú àwọn àlùfáà, gbogbo wọn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi.