Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Rameses

5 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Josẹfu sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Ejibiti, ó sì fún wọn ní ohun ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbègbè Ramesesi bí Farao ti pàṣẹ.

  2. Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pitomi àti Ramesesi gẹ́gẹ́ bí ìlú ìṣúra pamọ́ sí fún Farao.

  3. Àwọn ọmọ Israẹli sì rìn láti Ramesesi lọ sí Sukkoti. Àwọn ọkùnrin tó ń fi ẹsẹ̀ rìn tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ni iye láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé.

  4. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò láti Ramesesi ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ ìrékọjá. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Ejibiti.

  5. Àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Ramesesi wọ́n sì pàgọ́ sí Sukkoti.