Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Prayer Under Affliction: For deliverance
Àwọn ẹsẹ nípa For deliverance
Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi; èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa, má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀; Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, ni a ti fi iná sun, àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí? Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?
Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn, gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà, nítorí ìwọ ni ìyìn mi.